Tolulope Emmanuel, Osogbo
Owo ileese olopa ipinle Osun, eka ti Ileefe ti te baba eni odun merinlelaadota kan, Oluwagbemileke Awofisayo lori esun pe o ji isu onisu wa.
Aago meta osan ojo kinni osu kesan odun yii la gbo pe baba yii huwa naa ni abule Ajebamdele Likosi lagbegbe Ileefe.
Se ni olujejo dede wonu oko enikan ti won n pe ni Afolabi Oladimeji, to si wu isu ti owo re to egberun mewa naira.
Gbemileke ni oun ko jebi esun ole jija ti won fi kan oun sugbon agbejoro funleese olopa, Inspekito Emmanuel Abdullahi ni iwa to hu lodi, bee lo si nijiya nla labe ofin iwa odaran tipinle Osun.
Ogbeni Sunday Olagbaju to n gbenuso fun olujejo waa rawo ebe sile ejo lati faaye beeli sile fun un, o ni ko nii salo fungbejo, bee ni yoo fi awon oniduro to looko sile.
Majistreeti Olalekan Ijiyode waa faaye beeli sile pelu egberun lona ogun naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
O ni oniduro naa gbodo maa gbe lagbegbe ile ejo, ko si fi aworan pelebe meji sile.
Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ogbonjo osu kokanla odun yii.
No comments:
Post a Comment