IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 27 December 2017

Adebayo lu jibiti l'Osogbo, lo ba foju bale ejo

Tolulope Emmuel, Osogbo
Adebayo Surajudeen eni odun marundinlogota lo ti foju bale ejo majistreeti kan nilu Osogbo lori esun pe o lu obinrin kan ni jibiti.
Agbejoro funleese olopa lori esun naa, Ajayi Sunday salaye pe ojo ketalelogun osu kewa odun yii ni Adebayo huwa naa lagbegbe ijoba ibile Olorunda nilu Osogbo.
Ajayi ni se ni Adebayo gba egberun lona metalelaadota naira lowo arabinrin kan to n je Alabi Sarah pelu ileri pe oun yoo ta maalu kan fun un.
O ni esun naa lodi si ofin, bee lo si nijiya nla labe abala kerinlelogbon ofin iwa odaran tipinle Osun ti odun 2003.
Nigba ti won beere lowo Adebayo boya o jebi tabi ko jebi, o ni oun ko jebi awon esun ti won fi kan an.
Bakan naa ni agbejoro re, Barista Okobe Nnajite ro ile ejo lati faaye beeli sile fun olujejo lona irorun.
Majistreeti Ashiru Ayeni, ninu idajo re, faaye beeli sile fun olujejo pelu egberun lona aadota naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo ketalelogun osu kinni odun to n bo.

No comments:

Post a Comment