IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 27 December 2017

E ma dake adura o! Won ni omo Aare Buhari, Yusuf fori gbale lori okada l'Abuja


Iroyin to n te wa lowo bayii ti je ko di mimo pe omokunrin Aare Mohammed Buhari, Yusuf, ko tii laju saye latigba to ti subu lori okada nla ti won n pe ni Power Bike nilu Abuja.

A gbo pe se ni Yusuf fee ya ore re sile pelu keke naa to fi so ijanu nu, leyin to si ya kuro loju ona tan lo fori so ibikan legbee titi.

Yusuf ti won lo fi ori pelu awon eya ara miin pa lo koko daku lo rangbondan ko too di pe won ta iya re, Aisha lolobo.

Leyin eyi ni won gbe e lo sileewosan Cedarcrest latibi tireti wa pe won yoo ti gbe e kuro lorileede yii laipe funtoju loke okun.

No comments:

Post a Comment