IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 27 December 2017

Aye eyin osise ijoba nikan ko ni Aregbesola wa o - Oyatomi


Tolulope Emmanuel, Osogbo

Agbenuso fun egbe oselu APC nipinle Osun, Barista Kunle Oyatomi ti so pe ida marun pere ninu ida ogorun awon eeyan ipinle Osun ni won je osise ijoba, idi si niyii ti won ko fi gbodo maa reti pe kijoba na gbogbo owo le won lori.

Lasiko ti Oyatomi n fesi si oro kan ti won ni Seneto Iyiola Omisore ti egbe PDP so nilu Ilesa laipe yii pe ipinle osise ijoba nipinle Osun lo ti so pe oro rirun loro naa.

O ni loooto lawon osise ijoba se pataki sugbon kii se torii tiwon nikan nijoba se wa bikose fun gbogbo awon eeyan ti won wa nipinle Osun patapata.

O ni ko nii si ise idagbasoke kankan nipinle Osun lati tokasi to ba je pe owo osu nikan ni Gomina Rauf Aregbesola n fi gbogbo owo tijoba n ri san.

Oyatomi ni ole ati alailoye oloselu nikan ni yoo gbe idagbasoke eka kansoso ga laarin awon eka-eka to wa nipinle re.

O fi kun oro re pe awon anikanjopon pelu awon alainiyeninu ti won rogba yi Omooba Olagunsoye Oyinlola ka naa ni won koba a lasiko isejoba re eleyii to mu kijoba re da wahala ti Aregbesola n yanju lowo bayii sile.

No comments:

Post a Comment