Tolulope Emmanuel, Osogbo
Se lohun gbogbo duro daari bayii kaakiri awon ileese ijoba nipinle Osun pelu bi gbogbo awon osise ijoba se bere iyanselodi olojo gbooro lati beere fun eto won lowo ijoba.
Ojo karun osu yii ni won ti koko funjoba ni gbedeke ojo mokanlelogun lati dahun gbogbo ibeere ti won n beere nipa ekunrere owo osu won atawon owo ajemonu yooku.
A oo ranti pe lati nnkan odun meji seyin lawon osise ijoba l'Osun lati ipele kejo si ikewa ti n gba ida marundinlogorin ninu ida ogorun ti awon ipele kokanla si iketadinlogun si n gba idaji owo osu won.
Adehun tijoba atawon adari egbe osise se nigba naa ni pe ni kete ti eto oro aje ipinle Osun ba ti sorura ni gbogbo osise yoo bere sii gba ekunrere owo osu won.
Koda, gbogbo ona anfaani alajeseku tawon osise ni nigba naa lo di nitori ijoba ko san owo naa bo tile je pe won tun n yo o losoosu ninu owo kelekele ti won n gba.
Opolopo ipade nijoba atawon adari egbe osise ti se paapa lasiko tijoba apapo ba ti fun won lowoo Paris Club sugbon kaka kewe agbon de, lile lo n le sii.
Orin kansoso to n ti enu ijoba jade naa ni pe eto oro aje ko tii yipada fawon ati pe se ni kawon osise tubo ni aforiti titi ti osan yoo fi so didun fun won.
Idi niyen tawon osise yii fi fariga, won si funjoba ni gbedeke ipari osu kokanla pe nnkan gbodo yato.
Lose to koja nijoba tun pe won sipade sugbon bii igba teeyan n wo fiimu Babaajesa loro naa ri fun Gomina Aregbesola atawon omo igbimo re nigba tawon adari egbe osise ijoba yari kanle pe awon ko je amala ati iresi tijoba se kale fawon, owo osu lawon fee gba.
Nibi ipade ifikunlukun ohun ni won ti te tabili ounje sile repete niwajuu won, sugbon se lawon osise ohun fariga pe awon ko ba ti ounje wa, oro owo osu lawon waa yanju.
Ki gomina too mo nnkan to sele, awon osise ohun ti n jade leyokookan, koda, gbogbo arowa olori awon osise ijoba nipinle Osun, Dokita Olowogboyega Oyebade pe ki won tie meran je ni ko wo won leti, won lawon o jeun.
Ohun ti won n tenumo ni pe bawo nijoba yoo se maa fi owo osu pon awon loju, won ni awon ko gba owo osu ti ko nitumo mo, afi ekunrere. Bakan naa ni won ni afi kijoba gbese kuro lori oro awon tigbega ti to si, ki won si fun won nigbega sugbon waasi kannaa nijoba n wa fun won.
Nigba to di aaro ojo fraide to koja lolori awon osise ohun, Comreedi Adekomi kede pe iyanselodi olojo gbooro yoo bere nipinle Osun lojo ketadinlogbon osu kejila ati pe gbogbo osise lo gbodo tele ase naa.
Ninu iforowero ti a se pelu pupo ninu awon osise ijoba naa ti won ko lati daruko won, won ni ohun to bi awon ninu ju ni pe alaati idaji owo osu to wole lose to lo ni pe won ko sibe pe ara owo Paris Club eleeketa tijoba apapo sese san lawon fi san owo naa.
Won ni se lo ye kijoba to nife araalu lokan mo pe odidi owo osu lo ye koun san fun gbogbo awon osise paapa lasiko ti odun ti sunmole yii.
Amo sa, Komisanna feto iroyin, Adelani Bolarinwa ti ni iyanselodi naa ko nii bere tijoba yoo fi wa nnkan se soro naa.
No comments:
Post a Comment