Adajo majisreeti kan nilu Ado-Ekiti ti pase pe ki won loo fi Olukere ti Ikere-Ekiti, Oba Ganiyu Obasoyin pamo sogba ewon titi ti eka eto idajo yoo fi gba ile ejo nimoran lori igbese to to lori oba naa.
Kii se ori-ade yii nikan o, oun atawon marun miin ni, awon naa si ni Ajewole Sunday, Adetowoju Bode, Kayode Michael, Olowolafe Tola ati Aluko Taiwo.
Esun meta otooto to nii se pelu igbimopo huwa buburu, igbiyanju lati paayan ati ipaniyan ni won fi kan Olukere atawon marun to ku.
Oteeli Oba Obasoyin la gbo pe won n si lojoo fraide to koja nigba ti wahala ohun bere lasiko ti won ni oba naa soro kan to tako okan lara awon oludije funpo gomina latinu ilu naa.
Bi Obasoyin se soro ni wahala naa be sile ninu eyiti awon toogi kan ti dana sun oteeli ohun. Bayii la gbo pe awon ololufe Obasoyin naa loo mura ogun de ojoo Monde to koja.
Ija naa le debi wi pe okunrin kan to n je Kolade Adefemi je Olorun nipe lasiko naa eleyii to fa a ti won fi gbe oba naa.
Inspekito Johnson Okunade ni iwa ti kabiesi atawon yooku hu ohun lodi si ofin iwa odaran tipinle Ekiti ti odun 2012.
Agbejoro fawon olujejo, Ademola Adeyemi ro kootu lati faaye beeli sile fun won sugbon agbejoro olopa tako arowa naa.
Adajo Adesoji Adegboye ninu idajo re pase pe ki won loo fi Olukere atawon yooku pamo sogba ewon titi imoran lati eka eto idajo.
Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo kejo osu kinni odun to n bo.
No comments:
Post a Comment