Tolulope Emmanuel, Osogbo
Omo odun merinla kan, Omisore Ridwan atawon oree re, Wahab Moruf pelu Adedeji Abiodun lowo ti te bayii lori esun ole jija.
Nitori ojo ori Ridwan toun je omo odun merinla, kootu idile ni won mu un lo sugbon awon meji to ku ti farahan niwaju adajo ile ejo majistreeti kan nilu Osogbo lose to koja.
Ridwan, Moruf, eni odun metalelogun pelu Abiodun toun je omo odun mejidinlogbon ni won fesun kan pe won ji okada Bajaj kan eleyii to je ti Lateef Kolapo.
Sajenti Rasaki Abiodun to n soju ileese olopa ni kootu salaye pe lojo karun osu kejila odun yii lawon olujejo ji okada naa lagbegbe Ita-Olookan nilu Osogbo.
Esun merin otooto to nii se pelu idite, ole jija ati biba nnkan oninnkan je ni won fi kan awon olujejo naa.
Abiodun ni okada Kolapo ti won ji ohun lo ni nomba WEN 627 QD ati chasis nomba MDZA18A27CWJ68212.
Awon olujejo mejeeji lawon o jebi awon esun naa, bee ni agbejoro won, Nnajite Okobe ro ile ejo lati je koun gba beelo won.
Nigba to n gbe idajo re kale, adajo majistreeti naa, Sodamade Fatimah faaye beeli sile fun okookan awon olujejo pelu egberun lona igba naira ati oniduro kookan ni iye kannaa.
O waa sun igbejo siwaju di ojo kokanlelogbon osu kinni odun to n bo.
No comments:
Post a Comment