Tolulope Emmanuel, Osogbo
Owo ileese olopa ipinle Osun, eka ti Ileefe ti te omokunrin awako epo petiroolu kan, Seun Oladipupo lori esun pe o ji epo petiroolu egberun metalelogbon lita.
Seun, omo odun metalelogbon ni won fesun meta otooto kan eleyii to nii se pelu idite, ole jija ati didana sun tanka epo.
Sajenti Sunday Osanyintuyi to n soju ileese olopa lori oro naa salaye pe ni nnkan aago mejila oru ojo kan ninu osu kewa odun yii ni Seun huwa naa loju ona Ibadan Road nilu Ileefe.
Osanyintuyi ni se ni olujejo pelu enikan to ti na papa bora bayii jo ledi apo po, ti won si ji petiroolu ohun eleyii to je ti Alhaji Popoola Ogundoyin.
O fi kun oro re pe iye owo epo lita egberun lona metalelogbon ohun je milioonu merin ati egberun lona eedegbeta naira.
Osanyintuyi ni leyin ti won ji epo naa tan ni won dana sun oko tanka naa to ni nomba Ondo GKB 148 SA eleyii ti owo re to milioonu meedogun naira to si je ti Alhaji Ogundoyin bakan naa.
Agbejoro fun olujejo, Samuel Obi waa ro ile ejo lati faaye beeli sile fun olujejo leyin ti iyen so pe oun ko jebi esun ti won fi kan oun.
Ninu idajo re, Majistreeti Olalekan Ijiyode so pe oun ko lee faaye beeli sile fun un ayafi ti agbejoro re ba mu iwe wa lona to gba ba ofin mu.
Yato si eleyii, o ni ese ti Adebayo se ko kere rara. O waa pase pe ki won saa koko loo fi pamo sogba ewon na.
Leyin naa lo sun igbejo siwaju di ojo kejilelogun osu kinni odun to n bo.
No comments:
Post a Comment