IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 30 April 2025

Laarin oṣu meji, ijọba ibilẹ Irewọle nipinlẹ Ọṣun padanu alaga meji


Alaga ijọba ibilẹ Irewọle nigba kan ri, Honourable Gbadebọ Oyejide, ti jade laye.


Oyejide  tun ti figba kan ri wa nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun nibi to ti ṣoju awọn eeyan Irewọle/Iṣọkan.


Ọjọ Tusidee ọsẹ yii la gbọ pe ọkunrin oloṣelu ọmọbibi ilu Ikire naa dagbere faye pe o digbooṣe niluu Ibadan to n gbe.


Tẹ o ba gbagbe, lẹyin ti Oyejide kuro nile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun ni abẹnugan ile igbimọ aṣofin apapọ nigba naa, Hon. Yakubu Dogara, yan an gẹgẹ bii ọkan lara awọn oluranlọwọ pataki rẹ.


Lara awọn ti wọn ti ṣedaro rẹ ni aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Iwọ-Oorun Ọṣun nile igbimọ aṣofin agba, Akọgun Lere Oyewumi. O ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii ọlọpọlọ pipe oloṣelu to ti ko ipa manigbagbe ninu idagbasoke agbegbe naa.


Ẹ oo ranti pe inu oṣu keji ọdun yii ni Hon. Rẹmi Abass, toun naa jẹ alaga ijọba ibilẹ Irewọle, pade iku ojiji latọwọ awọn janduku ninuu sẹkiteriati kansu ọhun.

No comments:

Post a Comment