IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 1 May 2025

O ma ṣe o! Awọn janduku ṣeku pa Amọtẹkun kan l'Ọṣun


Awọn janduku agbebọn ti ran ọkan lara awọn ọmọ ajọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Lamidi Abiọdun, si ọrun ọsan gangan lọjọọ Wẹsidee ọgbọnjọ oṣu kẹrin ọdun yii.


Gbagedeọrọ gbọ pe awọn agbẹ ti wọn n dako ni Papa Farm to wa niluu Iwo ni wọn ranṣẹ si awọn Amọtẹkun pe awọn janduku kan n yọ awọn lẹnu lori oko naa.


Bayii ni ikọ Amọtẹkun niluu Iwo pẹlu awọn figilante agbegbe naa lọ sibẹ, ṣugbọn ṣe ni awọn janduku agbebọn yii, ti wọn ni ọkunrin kan to n jẹ Akeen Ọlọfa ko sodi, doju ija kọ wọn bi wọn ṣe debẹ.


Nigba ti gbogbo ibọn ti wọn yin si Lamidi ko wọle si i lara la gbọ pe wọn bẹrẹ si i ṣa a ladaa lori titi to fi gbẹmi mi nibẹ.


Bakan naa ni wọn ni wọn ko tii gburo ibi ti ọkan lara awọn figilante to lọ sibẹ wa bayii, ti ibọn si tun ba ọkunrin kan to n jẹ Sọla lẹsẹ.

No comments:

Post a Comment