IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 6 May 2025

Iṣẹ ti Gomina Adeleke ti ṣe l'Ọṣun ni yoo polongo ibo fun un - Adeniran


Agbarijọpọ awọn oluranlọwọ pataki fun Gomina Adeleke ti sọ pe ko si ẹnikẹni ti yoo gba ki awọn ẹgbẹ oṣelu alatako da ọkọ idagbasoke ipinlẹ pada sẹyin.


Nibi eto kan ti wọn ṣe lati fi atilẹyin wọn han fun gomina ni wọn ti sọ pe oniruuru iṣẹ akanṣe tijipba yii ti ṣe ni yoo polongo ibo saa keji fun gomina.


Latigba ti aṣofin to n ṣoju awọn eeyan Obokun ati Oriade nile igbimọ aṣofin apapọ l'Abuja, Ọnarebu Wọle Ọkẹ, ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party silẹ ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti n ki Gomina Ademọla Adeleke laya pe fila ma-wo-bẹ ni ko de, wọn ni gbọnin-gbọnin lawọn wa lẹyin rẹ.


Bi awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba ṣe n jẹjẹẹ atilẹyin fun gomina, ni awọn aṣofin apapọ naa sọ pe amọ ni Wọle Ọkẹ, ki i ṣe ara-ẹran.


Ni ti awọn oluranlọwọ pataki yii (Special Assistants), wọn ni ko si ohunkohun to le duro loju ọna saa keji fun Adeleke nitori iṣẹ to ti ṣe kaakiri ipinlẹ Ọṣun ni yoo ṣepolongo ibo fun un.


Alaga wọn, Ọnarebu Adeniran Sunday, ṣalaye pe anfaani tijọba Adeleke mu wọ Ọṣun jẹ arameeriri nitori ko si pe awọn ajeji ni wọn n kore Ọṣun mọ, inu Ọṣun ni wọn ti n na owo to n wọ ipinlẹ Ọṣun.


Adeniran sọ pẹlu idaniloju pe ko si ẹnikankan laarin awọn to tẹle Oluwọle Ọke lọ; yala latijọba ibilẹ rẹ tabi nibikibi nipinlẹ Ọṣun, o ni oun nikan lo da kuro ninu ẹgbẹ naa.


O ni aimọye awọn eto lawọn oluranlọwọ pataki ti gbe kalẹ fun awọn eeyan igberiko lati fi kin Gomina Adeleke lọwọ, bẹẹ ni awọn ko nii dawọ duro nitori ipinnu awọn ni pe gomina gbọdọ ṣe ẹlẹẹkeji.

No comments:

Post a Comment