IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 6 May 2025

Iṣẹ yoo bẹrẹ ni ibudo papakọ ofurufu Ido-Ọṣun laipẹ - Awolọla


Ọkan lara awọn aṣaaju ilu Ido-Ọṣun nijọba ibilẹ Ẹgbẹḍọrẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Abiọdun Awolọla, ti sọ pẹlu idaniloju pe laipẹ ni iṣẹ yoo bẹrẹ ni papakọ ofurufu to wa niluu naa.


Tẹ o ba gbagbe, loṣu diẹ sẹyin, ijọba ipinlẹ Ọṣun kede erongba rẹ lati gbe papakọ ofurufu naa kuro ni Ido-Ọṣun lọ si agbegbe kan niluu Ẹdẹ.


Awijare ijọba ipinlẹ Ọṣun nigba naa ni pe awọn kan ti kọle wọnuu ilẹ papakọ ofurufu naa, ilẹ to si sẹku ko le to fun iru iṣẹ akanṣe nla naa.


Ọrọ yii da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ laarin awọn ọmọ ilu mejeeji kaakiri agbaye. Bi awọn kan ṣe n sọ pe ki lo de to jẹ pe ilu gomina ni wọn fẹẹ gbe e lọ ti ki i ba ṣe pe ọrọ naa ni ọwọ kan oṣelu ninu, bẹẹ lawọn mi-in sọ pe ṣe ni ilu Ẹdẹ mọ-ọn-mọ fẹẹ fi ọwọ ọla gba ilu Ido-Ọṣun loju.


Amọ ṣa, Awolọla, ẹni to ti figba kan ri ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ naa nile igbimọ aṣofin Ọṣun ṣalaye pe ijọba apapọ ti yannana oniruuru lẹta ti awọn kọ si wọn, laipẹ si ni iṣẹ yoo bẹrẹ pada nibudo naa.


Lori eto ayẹyẹ iwuye ọba ilu naa, Ọba Ọlayinka Oyetunde Jokotọla, alaga ayẹyẹ ọhun, Ọnarebu Sanya Okunade, fi da gbogbo awọn ti yoo kopa ninu eto naa loju pe aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia wọn.


Okunade ṣalaye pe iṣẹlẹ to ṣẹlẹ kọja ti di afisẹyin, ko si si nnkan ti yoo di ayẹyẹ iwuye ti yoo waye lọjọ kẹrinlelogun oṣu karun-un ọhun lọwọ rara.


Lara awọn ti wọn n reti nibi ayẹyẹ naa ni Gomina Ademọla Adeleke, Abẹnugan Adewale Ẹgbẹdun, Kọneeli Theophilus Bamgboye, awọn ọmọbibi ilu Ido-Ọṣun nile-loko atawọn ololufẹ ilu naa.

No comments:

Post a Comment