Ọkan lara awọn to n tẹle eegun kan ti wọn n pe ni Orogunmeji niluu Ikirun nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ Ọṣun la gbọ pe ibọn osiṣẹ ajọ Amọtẹkun kan ti ran lọ sọrun bayii.
A gbọ pe lọjọ Mọnde, ọjọ kẹfa oṣu karun ọdun yii niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ lasiko ti wahala kan bẹ silẹ lẹyin eegun ọhun.
Gẹgẹ bi awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣe ṣalaye, lojiji ni wọn bẹrẹ si i lọ ibọn mọ amọtẹkun ti wọn pe lati maa daabo bo eegun Orogunmeji naa lọwọ, ti ibọn naa si dun gbau mọ ẹsẹ Abiọdun.
Gbogbo igbiyanju lati doola ẹmi rẹ lo ja si pabo nigba ti wọn gbe e deleewosan lọjọ naa, o gbẹmi mi laarọ ọjọ keji.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l'Ọṣun, Ọjẹlabi, fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti ranṣẹ si olori eegun orogunmeji fun ifọrọwanilẹnuwo.
No comments:
Post a Comment