Baba to bi ọmọdebinrin kan, Roseland Belony, ẹni ti iroyin rẹ gba ori intanẹẹti laipẹ yii nigba ti fidio ihooho rẹ nibi ti oun ati ọkunrin kan ti n ba ara wọn laṣẹpọ hu jade, ti ṣalaye pe ko si ootọ kankan ninu nnkan tawọn eeyan n sọ nipa ọmọ oun.
O ni lakọkọ, oun ki i ṣe pasitọ bi wọn ṣe n pariwo kaakiri, mẹkaniiki loun, bẹẹ loun tun maa n ṣe dẹrẹba ọkọ lẹẹkọọkan.
Ọkunrin yii, Serge Belony, ṣalaye lasiko ifọrọwerọ pẹlu Storm TV pe oniroyin ni Roseland, o maa n ṣe eto nipa eto-ẹkọ, bẹẹ lo si jẹ akọrin ati akinkanju ọdọ ninu ijọ ti awọn n lọ.
O sọ siwaju pe afẹsọna ọmọ oun ni ọmọkunrin to wa ninu fidio yẹn, gbogbo mọlẹbi ti mọ ọn, titi to fi de inu ṣọọṣi, ṣugbọn bii oṣu mẹjọ sẹyin lawọn alaṣẹ ijọ awọn sọ pe awọn ko faramọ imura ọmọkunrin naa, to si yọri si bi awọn mejeeji ṣe kọ ara wọn silẹ.
Belony tẹ siwaju pe ki i ṣe ọrẹkunrin Roseland lo gbe fidio naa sita, oṣu diẹ sẹyin lawọn ole da a lọna pẹlu ọkada, ti wọn si gba foonu rẹ ati gbogbo nnkan to gbe dani.
Awọn ole yii ni wọn gbe fidio naa jade lori foonu rẹ lẹyin ti wọn ṣeleri lati ba a lorukọ jẹ, ti wọn si beere owo nla.
Belony ni lootọ ni iṣẹlẹ naa da ibanujẹ si ọkan ọmọ oun, ṣugbọn awọn ṣugbaa rẹ, to si ti gba kamu, koda, o ti ki awọn ololufẹ rẹ lori ikanni ayelujara pe wọn kuu aduroti oun.
No comments:
Post a Comment