IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 14 May 2025

Lẹyin idajọ ile-ẹjọ, awọn janduku lu agbẹjọro atawọn oṣiṣẹ kootu lalubami l'Oṣogbo


Awọn mọlẹbi Oloogbe Sinatu Adeoye niluu Oṣogbo ti bu ẹnu atẹ lu bi awọn janduku kan ṣe dena de awọn oṣiṣẹ kootu atawọn amofin ti wọn fẹẹ gbe igbesẹ lori idajọ ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ọṣun laipẹ yii.


Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keji ọdun 1997 ni Onidajọ R. O. Yussuf ti gbe idajọ kan kalẹ pe ileeṣẹ Hephzibah Holdings Ltd atawọn oṣiṣẹ rẹ ko gbọdọ wọnuu ilẹ to jẹ ti oloogbe naa mọ laelae.


Awọn ilẹ eleyii ti iwe ipẹjọ to ni nọmba HOS/71/1993 ka wọn lapa ko pe wọn ko gbọdọ wọ mọ lo wa nijọba ibilẹ Ọlọrunda. O bẹrẹ lati Powerline titi de Dagbolu kọja si Bidire gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe akọsilẹ awọn wọlẹwọlẹ to ni nọmba OS/1378/2024/CP001.


Lẹyin ti asiko to yẹ ki awọn olujẹjọ fi pe ẹjọ kotẹmilọrun ti kọja ni awọn mọlẹbi Sinatu Adeoye pada si kootu lati gba agbara lati le awọn to wa lori ilẹ naa kuro.


Ogunjọ oṣu keji ọdun yii ni Onidajọ A. O. Adebiyi fun wọn laṣẹ lati lọọ ṣe ohun ti adajọ naa wi, ti kootu si fun wọn ni awọn oṣiṣẹ ti yoo tẹle wọn.


Amọ ṣa, wahala bẹ silẹ nigba ti wọn de agbegbe Jaye Filling Stations lọjọ kẹwaa oṣu karun ọdun yii, ṣe lawọn tọọgi fọn sita, ti wọn n beere fun aṣẹ ti wọn ni lati fi maa maaki ile tabi yọ paanu ile ati ṣọọbu.


Wọn fọwọ ba awọn amofin to wa nibẹ, wọn si sọ okuta lu awọn oṣiṣẹ kootu atawọn oniroyin ti wọn wa nibẹ lọjọ naa.


Nigba to n sọrọ lẹyin gbogbo wahala yii, aṣoju mọlébii Madam Sinatu, Ọgbẹni Najeem Popoọla sọ pe arifin si ile ẹjọ ni iwa tawọn janduku naa hu.


O ni bawo leeyan yoo ṣe lorilaya lati pagidina igbesẹ ti ile-ẹjọ ti fọwọ si, ti ki i ṣe pe awọn eeyan naa waa huwa atọwọda ara wọn.


Najeem ke si igbakeji ọga ọlọpaa patapata ni ẹkun kọkanla, kọmiṣanna ọlọpaa l'Ọṣun, alakoso ajọ Amọtẹkun atawọn oṣiṣẹ alaabo mi-in lati ri i pe wọn fi pampẹ ofin gbe gbogbo awọn to lọwọ ninu itaporogan naa, ki wọn fi wọn jofin lati le jẹ ẹkọ fun awọn ti wọn maa n tako aṣẹ ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment