Agbẹnusọ fun Gomina Adeleke, Mallam Ọlawale Rasheed ti sọ pe jinnijinni oniruuru ọkan-o-jọkan aṣeyọri tijọba to wa lori aleefa bayii ti ṣe l'Ọṣun lo bo akọwe apapọ ẹgbẹ oṣelu APC, Ajibọla Baṣiru, to fi n sọ oniruuru ọrọ to n sọ bayii.
Nigba to n fesi si ifọrọwanilẹnu wo ti Ajibọla ṣe lori tẹlifisan kan laipẹ yii ni Ọlawale sọ pe ọrọ naa ṣe Ajibọla atawọn aṣaaju ẹgbẹ APC ni kayeefi debii wipe ti wọn ba ri nnkan funfun bayii, wọn a ni dudu ni.
O ni wọn koda bi awọn araale wọn ba n sọ otitọ fun wọn nipa iṣejọba Adeleke, wọn ko nii gba wọn gbọ nitorii ṣibaṣibo to ti ba wọn.
Ọlawale sọ siwaju pe ipo kẹtalelọgbọn nipinlẹ Ọṣun wa ninu idanwo JAMB laarin ọdun 2018 si 2022 lasiko iṣejọba APC, ṣugbọn ni bayii, Ọṣun ti bọ si ipo keje, sibẹ, Ajibọla ko ri nnkan iwuri ninu iyẹn. Bakan naa si ni Ọṣun ṣe ipo kinni niha Iwọ Oorun Guusu Naijiria lori eto ilera alabọde labẹ iṣejọba Adeleke, sibẹ, awawi ni Ajibọla n sọ.
O ni iṣejọba Adeleke tun da oju-ọna to kọja si ile Ajibọla Baṣiru niluu Oṣogbo lati kọ ọ bi wọn ṣe n ṣejọba alakoyawọ yatọ si koto gelegele to wa loju ọna yẹn fun gbogbo igba ti APC fi wa nijọba.
Ọlawale, ẹni to kẹdun pẹlu Ajibọla lorii hilahilo ti awọn ọmọlẹyin 'AMBO'' ko o si bayii, sọ fun un pe arun otutu aṣeyọri Adeleke to mu un yii ki i ṣe eyi to le san kiakia, afi ko tete gba pe ẹni ti Ọlọrun ati awọn araalu n fẹ ni Adeleke, yoo si lo ọdun mẹjọ rẹ pe perepere.
No comments:
Post a Comment