IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 8 May 2025

Nipinlẹ Ondo, adajọ ni ki kabiesi atawọn oloye rẹ lọ maa naju lọgba ẹwọn


Adajọ majisreeti kan niluu Akurẹ nipinlẹ Ondo ti ni ki ọkunrin kan to n pe ara rẹ ni ọba, Adekọlajọ Aladeṣeyi atawọn oloye rẹ meji lọ gbatẹgun lọgba ẹwọn bayii.


Ẹsun ti wọn fi kan awọn mẹtẹẹta ni pe wọn da wahala silẹ ninu ilu Ijare nijọba ibilẹ Ifẹlodun nipinlẹ naa.


Gẹgẹ bi Babatunde Ajiboye to jẹ aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa to gbe Aladeṣeyi, Faṣore Lawrence ati Adegbenro Akanle wa si kootu ṣe sọ, lọjọ kẹẹdogun oṣu kẹrin ọdun yii ni wọn huwa naa.


Ajiboye ṣalaye pe ṣe lawọn ijoye mejeeji yii kede, ti wọn si yan Aladeṣeyi gẹgẹ bii Olujare ti ilu Ijare lai gba aṣẹ lọdọ ijọba tabi igbimọ lọbalọba, eleyii to si da wahala silẹ nibẹ.


Lẹyin ti awọn métẹẹta sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun naa ni agbẹjọro wọn, Adelankẹ Aknirata bẹ kootu lati fun wón ni beeli ti ko nira.


O ni wọn ko nii sa lọ nitori ẹni to lorukọ rere lawujọ lawọn mẹtẹẹta ati pe ẹṣun ti wọn fi kan wọn tọ si beeli.


Amọ ọkan lara awọn afọbajẹ ilu naa sọ fun kootu pe wahala nla yoo ṣẹlẹ ti wọn ba gba beeli awọn mẹtẹẹta. O ni inu ibẹrubojo ni gbogbo ilu wa latari bi awọn janduku ti wọn n ṣiṣẹ fun ọkunrin to n pe ara rẹ lọba yii ṣe n leri kaakiri.


Onidajọ Jaiyeọla Ogungade sọ ninu idajọ rẹ pe ki wọn lọọ fi awọn ọkunrin métẹẹta pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kejila oṣu karun ti yoo gbe idajọ kalẹ lori ọrọ beeli wọn.

No comments:

Post a Comment