Lọwọlọwọ bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti ti gbogbo ọfiisi awọn ẹṣọ alaabo Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun to wa kaakiri ijọba ibilẹ ati olu ileeṣẹ wọn l'Oṣogbo pa.
Gbagedeọrọ gbọ pe lati Abuja lawọn ọlọpaa naa ti wa.
Awọn ọmọ ajọ Amọtẹkun ti wọn to ogun(20) la gbọ pe wọn wa lakolo ọlọpaa bayii.
Ṣugbọn gbogbo igbiyanju lati ri alakoso wọn, Dokita Ọmọyẹle, mu lo ja si pabo.
Tẹ o ba gbagbe, ọsẹ to kọja lawọn Amọtẹkun pa eeyan mẹta niluu Akinlalu, ti ọpọ si farapa.
No comments:
Post a Comment