Ọkan pataki lara awọn oludije funpo gomina ipinlẹ Ọṣun latinu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), Benedict Olugboyega Alabi, ti sọ pe iyatọ yoo ba iṣẹ agbẹ ti oun ba lanfaani lati di gomina ipinlẹ Ọṣun lọdun 2026.
Alabi, ẹni to jẹ igbakeji gomina ana nipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, sọ pe lara erongba oun ni lati sọ iṣẹ agbẹ di ti igbalode, ti yoo si mu un ko rọrun fun awọn agbẹ lati ṣamulo awọn nnkan idako lọna irọrun.
O ni ti iṣẹ agbẹ ba di ti igbalode, ounjẹ yoo pọ yanturu fun awọn araalu, bẹẹ ni yoo tun jẹ orisun ipese iṣẹ nitori pupọ awọn to ti sa kuro nidi iṣẹ agbẹ nitorii wahala to wa nibẹ yoo pada si oko.
Alabi fi kun ọrọ rẹ pe iṣejọba oun yoo ṣatunṣe gbogbo oju-ọna to so awọn ilu nlanla pọ mọ awọn igberiko, ki awọn agbẹ le lanfaani lati ko ere-oko wa sile fun tita lai si idaamu loju ọna.
Gẹgẹ bo ṣe wi, ọkan lara ọna lati le jẹ ki eto ọrọ-aje ipinlẹ Ọṣun rugọgọ sii ni ki iyatọ ba iṣọwọṣiṣẹ awọn agbẹ, ti wọn ba si ti lanfaani si awọn irinṣẹ idako igbalode, ounjẹ yoo pọ, eto ọrọ-aje yoo si yatọ laarin ilu.
Alabi tẹ siwaju pe gbogbo awọn ohun amayedẹrun to wa lawọn ilu nlanla nijọba oun yoo ṣe fun awọn to wa kaakiri igberiko lati le jẹ ki awọn naa ni imọlara iṣejọba tiwantiwa to ka wọn si.
O ni oun nigbagbọ pe, pẹlu ifọwọsowọpọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun, gbogbo erongba oun yii yoo di mimuṣẹ.
No comments:
Post a Comment