![]() |
| Omooba Oyinlola |
Gomina ipinle Osun tele,
Omooba Olagunsoye Oyinlola ti so pe se ni ki Ojogbon Wole Soyinka loo wa eni ti
yoo fi oye kikun ye e nipa ibudo asa ile adulawo to wa nilu Osogbo dipo bo se n
fonnu kaakiri pe oun ni alaga ibudo naa.
Oyinlola so pe iyalenu lo je fun oun pelu igbese ti Soyinka gbe laipe yii nipa siso fawon oniroyin pe se ni oun (Oyinlola) fee so ibudo naa di ogun idile.
O ni ohun ti ko ye ojogbon yii nipa ibudo naa poju ohun to ye e lo, ati pe ko setan lati ni imo nipa re pelu bi ko se faaye gba ifikunlukun lori oro naa latigba to ti n janpata lorii re.
Oyinlola ni ohun ti ko je ki oro naa koko jo oun loju ni pe gbogbo ipa ati ipo ni Soyinka fi ja pe ki ajo NESCO mase fowosi ibudo naa funpinle Osun sugbon to je pe leyin ipade apero to waye ni Paris ni oro ibudo naa ti yanju funpinle Osun.
O fi kun oro re pe adehun laarin molebi Ulli Beiers pelu ijoba apapo orileede Naijiria to si je pe awon ipin merin sankosanko ni won lenu lori e, awon naa si ni ijoba ipinle Osun nibi tibudo asa ile adulawo ohun wa, ijoba apapo orileede yii, ajo UNESCO atidile Beier.
Bakan naa ni Oyinlola fidii re mule pe ibudo naa kiibse fun enikeni bikose eru ipinle Osun ati tijobq apapo, ti won si ti fi oruko re sile pelu Corporate Affairs Commission labee Companies and Allied Matters Act (CAMA) eleyii to mu un soro fun enikeni lati gbe igbese kankan lodi si akosile naa.
A oo ranti pe Omooba Oyinlola ni asoju idile Beier fowosi gege bii alaga titi lae fun ibudo naa lati fi moriri babaa re, Olokuku, sugbon nigba ti Gomina Aregbesola dori aleefa lo fagile adehun yii to si fi kede yiyan Ojogbon Soyinka gege bii alaga ibudo naa. Oyinlola atawon omo igbimo ibudo naa lo sile ejo, ile ejo si da won lare, sibe Aregbesola ko tun ipinnu re se.
Leyin ti Oyinlola darapo mo egbee APC, o tun loo ba Aregbesola lori oro naa, latigba naa si ni ara ko ti rokun, ti ara ko ro adiye, ko see se fun Aregbesola lati pounda lorii Soyinka, bee ni Oyinlola naa ni ko seni to lee gba alaga ibudo naa lowo oun.

No comments:
Post a Comment