IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 20 October 2015

Aregbesola gbe awon oluko ile eko giga l'Osun lo si kootu

Latari bi awon oluko ti won n sise lawon ile eko giga mereerin to je tijoba ipinle Osun se so pe dandan oogun alaaru ko gbodo gbe, ti won si ti wa lenu iyanselodi fun opolopo osu seyin, ijoba ipinle Osun ti gbe ejo awon eeyan ohun lo si kootu awon osise, iyen Industrial Court. Yato si pe gomina fesun kan awon eeyan naa pe won ko tele ase ijoba pe ki won pada senu ise laitii gba owo osu won, o tun so pe iwe ofin awon osise ko mo egbee won ti won pe ni Council of Academic Staff Union of Osun State Owned Tertiary Institutions. Sugbon awon oluko naa so pe eepo epa awon to lati di ohun aijiiri lodo ijoba Osun leyin to ti ba egbe naa dunadura fun opolopo igba ati pe egbe naa setan lati pade Aregbesola ni kootu nitori pe ko si iye ihale kankan to le fi ko awon ni papamora lati pada senu ise.

No comments:

Post a Comment