IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 14 October 2015

Idi ti Buhari fi le Adewole, minista lati Osun, kuro ni Naijiria lodun 1985

Odun yii gan an lo pe ogbon odun ti Ojogbon Isaac Folorunso Adewole, eni ti Aare Buhari mu bayii gege bii minista latipinle Osun salo fun emii re lasiko tisejoba ologun Buhari pase pe oun fee rii l'oku tabi aaye.
Isele naa sele lasiko ti Adewole je aare egbe awon onisegun oyinbo, iyen Association of the Resident Doctors ni UCH, to si kede iyanselodi awon dokita kaakiri gbogbo Naijiria, o sa kuro lorileede yii lo si London ko too di pe ijoba Babangida forijin gbogbo awon dokita ti won n wa nigba naa, to si pada si Naijiria leyin odun kan ati osu meta leyin odi.
Omobibi ilu Ilesa ni Adewole, omo odun mokanlelogota ni, onisowo ni baba re lagbegbe Okeesa nilu Ilesa. Ileewe Ilesa Grammar School lo si ti jade. Iyalenu ni ibii re nitori pe inuu moto dokita abele kan, Ogbeni Abimbola ni iya re toun naa je onisowo bii si ki won to de ileewosan lojo naa.
Iyawo meji lo ni, noosi niyawo re akooko, nigba ti ekeji je dokita. Odun un 1999 lo gboye Ojogbon sugbon won bere kikaa re fun un lati odun un 1997. To ba je pe ko se ise onisegun oyinbo to n ri si ohun gbogbo to nii se pelu oro oyun ni, ise agbe tabi ko maa tun oko oju ofurufu se lo tun wu u lokan.
O feran lati maa kawe, paapa iwe akosile nipa awon eeyan nla nla ati oselu, o feran ko maa wo sinima paapa Africa Magic, o feran ko maa rinrin ajo kaakiri, ko si si ibi ti ko ti le sun nitori pe o ni ebun oorun.
O ti pinnu pe iwasu ihinrere loun yoo mu lokunkundun leyin to pari saa re gege bii oga agba ileewe University of Ibadan losu die seyin ko too di pe Aare Mohammadu Buhari ko oruko re sowo sawon asofin agba gege bii okan lara awon minista tijoba re fee lo bayii.
@@@@@@@@

No comments:

Post a Comment