IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 14 October 2015

Buhari ti yo oruko Ahmed Ibeto kuro ninu awon minista

Aare Mohammodu Buhari ti yo oruko okan lara awon minista mokanlelogun to fi ranse sile igbimo asofin agba lose to koja.
Laaro yii ni aare fi leta kan sowo si Seneto Bukola Saraki to je aare ile igbimo asofin agba pe ki won yo oruko igbakeji gomina ipinle Niger tele, Ahmed Musa Ibeto kuro ninu oruko awon ti won yoo se ayewo fun.
Idi ti aare fi gbe igbese yii ko tii di mimo fun enikeni. Ni bayii, oruko awon minista naa ti din eyokan, o je merindinlogoji.

No comments:

Post a Comment