IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 27 October 2015

Mosun Filani Oduoye ni ko si ija laarin oun atoko oun


Gbajumo osere tiata Yoruba nni, Mosun Filani Oduoye ti so pe iro funfun balau ni aheso to n lo kaakiri pe gbun gbun gbun wa laarin oun atoko oun, Kayode Oduoye.
Mosun so nilu Osogbo lose to koja pe iyalenu lo je fun oun lati ka iroyin naa nitori pe oun ko si lori ero ayelujara kankan yala facebook, twitter, whatsapp ati bee bee lo.
O ni lati odun un 2009 loun ti ko ohunkohun sori ero ayelujara, oun ko si mo enikeni to n lo oruko oun lati ko nnkan sorii facebook.
Gege bi Mosun se salaye "Ko si wahala kankan laarin emi ati oko mi, awon ore mi ti n pe mi kaakiri nipa iroyin naa, n ko mo erongba awon ti won n gbe iroyin yen kaakiri, orun 2009 ni mo ti lo facebook keyin".
A oo ranti pe laipe yii laheso naa kaakiri pe o dabi eni pe nnkan ko lo deede mo laarin Mosun Filani ati oko re to je omobibi ilu Ikirun nipinle Osun.
Ohun ti awon agbesunmomi naa n so ni pe osere tiata Yoruba pupa naa ko nnkankan sorii facebook re pe o san keeyan wa laaye araa re, ko se ohun to wu u ju ko gbe igbesi aye re le ori elomiin lo ati pe o daa keeyan ma si nile oko ju ko wa nibe lai ni ifokanbale lo.
Sugbon Mosun, omobibi ilu Ekiti so pe iro funfun balau ni aheso naa ati pe kampe ni ife wa laarin oun ati oko oun.


No comments:

Post a Comment