IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 28 October 2015

Won ko tii ri Ojogbon Olomo o



Egbe osise ni yunifasiti Obafemi Awolowo nilu Ileefe, iyen ASUU ti ke gbajare sijoba apapo ati oga agba olopa lorileede yii lati ba won sawari Ojogbon James Bolarinwa Olomo eni to ti dawati lati nnkan odun meji seyin.
Gege bi alaga egbe naa, Dokita Caleb Aborisade se salaye, o dabi eni pe bojuboju nileese olopa orileede yii n fi oro naa se tori pe gbogbo ariwo awon pe ki won sise papo pelu ileese ibaraenisoro Glo lati mo awon ipe ti ojogbon jaa gba keyin ko too dawati ni won ko kobiara si.
Aborisade ni iyalenu patapata lo je fun ASUU pe titi dasiko yii won ko tii gburo ati oku ati aaye ojogbon ninu imo Nuclear and Medical Physics naa, ti ko si seni to lee so ni pato ibi to wole si.
Won fi kun oro won pe gbogbo awon ileewosan to wa nilu Eket nipinle Akwa Ibom ti ojogbon naa lo ko too dawati lawon ti lo boya enikeni wa nile igbokusii won tabi to nijamba moto, sugbon ko seni to jo Ojogbon Olomo nibe.
Bakan naa lo ni ihuwasi alabojuto oteeli ti ojogbon naa sun nilu Eket mu ifura lowo peluu bo se so je pe ile ikonkan pamo si ni won loo gbe baagi ojogbon naa si leyin ti won ko ri ko pada wa sibe ti won ko si fi oro naa to awon olopa leti.
O fi kun oro re pe gbogbo awon ijo Katoliiki to wa nipinle Akwa Ibom lawon ti fi oro naa to leti lati le je ki enikeni to ba kofiri ojogbon naa nibikibi fi to awon agbofinro leti.
A oo ranti pe lojo ketadinlogun osu kewa odun un 2013 ni Ojogbon Olomo kuro nile re lo silu Eket nipinle Akwa Ibom nibi ti won ti fiwe pe e gege bii olubadamoran funleese elepo robi kan nibe.
Sugbon logunjo osu naa lo kuro ninu oteeli Farlem to de si, ti ko si seni to gburo ibi to wa titi doni.
ASUU ileewe OAU wa n ro enikeni to ba ba won ri ojogbon omobibi ipinle Osun naa lati fi to ileese olopa to ba wa nitosi ibe leti Ojogbon Olomo nibe.

No comments:

Post a Comment