Ni bayii to ti din ni ose meji ti won yoo kede Ooni tuntun fun ilu Ileefe, idile Giesi ti fi oruko ogun eeyan ti won kunju osunwon, ti won si yege lasiko ayewo sowo si awon afobaje.
Omooba metadinlogoji latinu idile naa ni won jade pe awon nife sipo Ooni sugbon leyin ayewo oniruuru, awon agbaagba ile ja awon metadinlogun, won si gba ogun wole.
Ninu oruko ogun ti won ti fi sowo yii ni awon afobaje yoo ti mu ENIKANSOSO ti Ifa ba yan lati di Ooni, eni yii naa ni won yoo fi oruko re ranse si Gomina Aregbesola fun ikede.

No comments:
Post a Comment