IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 25 October 2015

Ori ko Oloye Obasanjo yo ninu ijamba moto

Leyin odun mewa geerege ti okan pataki lara awon iyawo aare orileede yii tele, Oloye Olusegun Obasanjo, ori ko baba yii yo ninu ijamba moto ti iba gbemi e.
A gbo pe Obasanjo kuro nilu Abeokuta laaro ojoo Satide to koja leyin to kopa ninu isin iranti ti won se fun Oloogbe Stella Obasanjo eni to ku lodun mewa seyin, to si forile ilu Eko lati kopa nibi ayeye ojobii ogorin odun ti Sir Keshington Adebutu ti gbogbo eeyan mo si Baba Ijebu.
Bi won se koja iyana to lo sona Sagamu die ni taya oko Jiipu ti baba wa ninu e fo lori ere, bi kii baa sii se Olorun ni, oro iba yiwo.
Moto miin ninu awon to tele Obasanjo lo gbe baba debi ayeye ojobi to n lo.

No comments:

Post a Comment