Igbeyawo alarinrin waye laarin okan lara awon omokunrin Oba Okunade Sijuwade, Omooba Gbite Sijuwade pelu ololufe re, Dolapo Olowu to je omo oloselu pataki kan nipinle Osun, Oloye Oluremi Olowu.
Ileejosin St John Church, Hyde Park nilu London nigbeyawo naa ti waye, nigba ti awejewemu igbeyawo si waye ni Dorchester Hotel, Park Lane West End nilu London bakan naa.
Owa Obokun ti ile Ijesa, Oba Gabriel Aromolaran lo ko awon oba alaye sodi lo sibi ayeye naa. Lara awon oba to tun wa nibe ni Olufon ti Ifon Orolu, Oba Almoruf Magbagbeola atawon mii.
Bakan naa ni Senato Iyiola Omisore ati Omooba Diran Odeyemi naa ko gbeyin nibe.
A oo ranti pe ayeye mo-mi-n-mo o awon ololufe mejeeji yii ni won dajoo re sona ti Oba Okunade fi waja lose to ye ki won se ayeye naa, bo tile je pe won se e nipinle Eko nigba naa kawon eeyan ma baa fura pe baba ti rewale asa, won sese waa lo fe e loju fawon tiwon nilu London ni.

No comments:
Post a Comment