IROYIN YAJOYAJO

Friday, 30 October 2015

Rueben Abati lo koba Goodluck Jonathan - Clark

Olori awon eya Ijaw lorileede yii, Oloye Edwin Clark ti so gbangba pe ojukokoro ni Reuben Abati to je agbenuso fun aare ana lorileede yii, Omowe Goodluck Jonathan fi koba isejoba re ti ko fi rowo mu ninu eto idibo osu keta odun yii.
Clark ni gbogbo imoran oun pe ki Abati je kawon adari ileese iroyin gbogbo to wa lorileere yii mo ohun gbogbo nipa isejoba Goodluck ni ko tele rara.
O fi kun oro re pe opo igba loun ba Abati so pe ko ranse sawon eeyan naa lati ba won sepade ni Aso Rock sugbon to je pe torii iwa iwora re ni ko je ko pe won. O waa so fun Abati pe ko mase fi ikanra aita oja re mu aje toun o.
Abati lo koko bere itaporogan yii nigba to so laipe yii pe iyalenu lo je foun pe Clark ko pe Jonathan ni 'omo' re mo latigba tisejoba ti bo lowoo PDP.

No comments:

Post a Comment