IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 3 November 2015

Awon aafa ti won pa omo odun merin nilu Iragbiji ti n jejo

Adajo majistreeti ilu Iragbiji nijoba ibile Boripe nipinle Osun ti ni kawon aafa meta pelu baba agbalagba kan towo te lori esun pe won pa Teslim Bakare omo odun merin loo fenu fera logba ewon titi ti igbejo yoo tun fi waye lori oro won.
Awon aafa naa, Tajudeen Ganiyu, Wasiu Agboola ati Aremu Moshood ni won lo sagbegbe Agbelekale nilu Iragbiji, won so Teslim pe ko senikankan nitosi e, won si sewo sii pe ko waa gba bisikiiti.
Nigba ti omo yii si rii pe irungbon won jo ti awon aafa ti won maa n ko oun ni keu, o lo sodoo won. Bayii ni won gbe e, o di agbegbe Oke-Mori ni Otapete nibi ti mosalaasi kan ti won ti n kirun wa.
Leyin mosalaasi yii ni won ti da Teslim dubule, won dunbu e bii eran ileya, won si gba ejee re sinu ike kan. Ko seni to mo bi oro naa se je sugbon aaro ojokeji lawon araalu bere sii ri iwa ibi tawon eeyan naa hu kaakiri orii foonu won.
Lasiko iwadi lowo tun te baba agba eni ogota odun kan, Ganiyu Abidoye tiwadi fi han pe won jo n sise naa ni.
E ka ekunrere ninu Alaroye ose yii.

No comments:

Post a Comment