IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 3 November 2015

Olokada kan ku nibi ti won ti n sajoyo oba tuntun n'Ileefe

Bi ojoo wesde to koja, iyen ojo kejidinlogbon osu kewa odun yii se je ojoo manigbagbe fun idile Oba Adeyeye Ogunwusi pelu bo se je pe ojo naa lo wolu Ileefe pelu ayo nla gege bii Ooni, naa lo je ojoo manigbagbe fundile omokunrin olokada kan to padanu emii re nibi ajoyo naa.
Opolopo awon olokada ni won ri ise se lojo naa ju bo se maa n ri tele lo, won si n gbe awon eeyan latibikan si ibomiin, elomiin le gbe eeyan meji, bee lo je pe elomiin n gbe eeyan meta leekansoso.
Nigba ti Oba Ogunwusi de si Toll Gate Ajebamdele nibi ti baba re ti fa a le won afobaje lowo, awon eeyan ti won wa nibe bere sii gbera lati maa lo sinu ilu nitorii sunkere fakere oko to ti wa loju ona.
Bi awon onimoto se n foju ona to ye ki won gba sile loo gba ona olona naa lawon olokada naa n gba ona to wu won, ere asapejude ni gbogbo won si n sa lati fi bi ayo won se kun to nipa oba tuntun naa han.
Nigba to ku die keeyan de Mayfair ni onimoto kan pelu olokada toun gbe eeyan meji fori soraa won.
Ijamba naa po tobe gee to fi je pe loju ese ni olokada naa gbemi mi, ese kan aye ese kan orun ni okan lara awon meji to gbe seyin wa, nigba ti eniketa ko lee da dide nile mo.
Se ni imuu moto naa ja segbe titi, ti oju omokunrin olokada ti ko ti lee ju omo odun merindinlogbon lo naa si yo jade lagbarii re.
Bi awon olubanikedun se sunmo ibi tawon ti won lugbadi ijamba naa wa ti won rii pe olokada ti jade laye ni won bere sii wa moto tiwon yoo fi ko awon meji to ku peluu dereba moto naa lo sileewosan.
Sibe, eleyii ko da ayeye duro rara, se lawon ti won to lowoowo sojuu titi ti won n reti Ooni tuntun n korin lo, ti ohun gbogbo si n lo gege bi won ti setoo re sile.

No comments:

Post a Comment