IROYIN YAJOYAJO

Tuesday, 10 November 2015

L'Osogbo, Moshood jabo latori opo ina; lo ba ku patapata

Ariwo ikunle abiyamo oo lawon eeyan agbegbe Zone C Road 7 ni Ago Ayo Community lagbegbe Garaaji Ilesa nilu Osogbo n pa nigba ti baba olomo marun kan jabo latori opo ina to n ba won tun se.
Ise awon to n tun firiiji atawon nnkan elo inu ile miin se ni Ogbeni Moshood ti gbogbo awon eeyan mo si Majoko (dont sit down) ko, to si n se sugbon o ni imo nipa titun ina ijoba naa se.
Latigba to ti ko de adugbo yen lawon eeyan ti mo on gege bii akinkanju, ti ohunkohun ba si ti se ina won, yala lori opo ni tabi ninu ile, won maa n ranse si Majoko, yoo si ba won se e.
Ojoo Tusde to koja yii, iyen ojo keta osu kokanla ti a wa yii ni oro yiwo, se la
gbo pe awon waya meji sun le araa won latari afefe ojo to fe lagbegbe naa lojoo Monde, eleyii tawon araadugbo si rii pe o le sakoba fun ina won.
Ko si ina ladugbo naa ni gbogbo idaji ojo naa, nigba to di nnkan aago mesan aaro ojoo Tusde, won ranse si Majoko pe ko waa ba won la awon waya naa, nigba to si je pe orun n ya bo ti kii se oro enikan loro ina naa, o gba lati ba won se.
Bo se gbe akaba (ladder) de idi opo ohun, o so funyawo re pe ko loo ba oun mu ibowo (glove) toun maa n fi se ina wa, iyen naa si lo sinu ile lati loo mu un.
Sugbon kiyawo too pade de, Majoko ro o pe oun yoo sare se ina naa lailo ibowo ko too di pe won yoo mu ina de, bee lo gori opo, to n fa waya ina, awon okunrin kookan ladugbo naa si n wo o loke.
Ko tii ju iseju merin to bere atunse yii lo ti won muna de, se ni ina so majoko soke lati ori opo, soose lo si n bo nile lailee du ara rara.
Bo se jabo sile lawon okunrin ti won wa nibe gbe e, o dileewosan kan to wa lagbegbe naa boya awon lee ri emii re doola, sugbon epa ko boro mo, majoko ti jade laye, o ti loo joko lorun.

No comments:

Post a Comment