Egbe awon akekojade nile eko giga mereerin to wa nipinle Osun; Ileewe gbogbonise ilu Iree, ti Imo ero to wa nilu Esa Oke, tawon oluko agba to wa nilu Ilesa pelu eyi to wa nilu Ila Orangun ti ke gbajare pe oko iparun nijoba ipinle Osun n ran oko eto eko ipinle naa lo bayii.
Gege bi agbenuso awon egbe naa to tun je aare tilu Iree, Oloye (Arabinrin) Mobola Odebode se so, awon igbese ti Gomina Aregbesola n gbe lori awon ile eko giga mereerin naa je eyi ti yoo mu ifaseyin ba eto eko nipinle Osun ti awon eekan ilu ba kuna lati tete da si oro naa.
Mobola, eni to soro yii loruko awon aare awon akekojade awon ile eko giga to ku, o ni iyalenu lo je fawon pe ijoba ipinle Osun ti kowe sajo JAMB lati yo oruko awon ile eko mereerin kuro ninu silaboosi, eleyii to tumo si pe ko si omo kankan ti yoo lanfaani lati wo awon ile eko naa fun odidi odun meji.
Yato si pe igbese yii yoo mu eebu eyin ba ireti opolopo awon akeko ti won fee wole sawon ile eko wonyii, Mobola ni gbogbo oro aje awon araalu mereerin yii ni yoo wo patapata.
O fi kun oro re pe aimoye igbese lawon ti gbe lati le je kijoba ri idi ti ko fi si anfaani kankan ninu erongba re lati da awon ileewe wonyii po sugbon to je pe pabo ni gbogbo re n ja si.
O ni awon ti be awon lookolooko ilu lowe si gomina, awon ti lo sodi awon oba alaye, awon ti ba awon araalu soro, bee lawon ti ran awon oloselu sii, sugbon se lo n yi won, to si n so pe ko si nnkan to jo dida awon ileewe naa papo.
Arabinrin yii ni igbese tijoba bere nipa dida awon osise duro lawon ile eko mereerin naa lo tubo fi idi oro naa mule nitori pe awon osise bii otalelugba nijoba ti fun niwee gbele-e nile eko olukoni agba tilu Ilesa ati ti Ila Orangun bayii.
Egbe naa waa ro Gomina Aregbesola lati tun ero re pa, bakan naa ni won kesi awon ti won mo oriki ti gomina nje lati ba a soro ko too di pe nnkan yoo bo sori fawon eeyan ipinle Osun.

No comments:
Post a Comment