IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 16 December 2015

L'Ekoo, adajo ti ju Gani to fee fipa ba Taiwo lopo sewon odun merin ataabo

Adajo majistreeti kan nipinle Eko ti pase pe ki okunrin eni odun mokandinlogbon, Ganiyu Awaawu loo fi aso penpe roko oba fun odidi odun merin ataabo, ko si tun san owo itanran egberun marun lori esun pe o fee fipa ba omo olonje kan, Taiwo Ogundipo lasepo.
Gegebi agbejoro funleese olopa, Inspekito Clifford Ogu se wi, nnkan aago merin irole ojo kejidinlogbon osu kejo odun yii ni Gani huwa naa nigba to pe Taiwo to si ra onje lowoo re lagbegbe Safuratu Yakubu Way, Ayobo.
Leyin to je ounje tan lo so fun Taiwo omo odun meedogbon pe ko waa gba owo ninu ile kan sugbon to je pe se lo fagbara fa aso ya mo on lara nibe to si fee fipa ba a laseoo, ariwo ti iyen pa lo ta awon araadugbo lolobo ti won fi sare loo gba a sile nibe.
Leyin eyi ni won fa Gani le awon agbofinro lowo. Esun merin otooto ni won fi kan an, adajo majistreeti agbegbe Ogba, Arabinrin T. Akanni waa pase pe ko san egberun marun naira fun esun akooko, yoo si lo sewon odun merin ataabo leralera fesun meta to ku.

No comments:

Post a Comment