IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 24 November 2016

Inuu Mosalasi ni Akeem ti ji foonu, osu mesan ni yoo lo lewon


Lasiko ti gbogbo awon olujosin toooto n sadura lowo ni mosalaasi kan nilu Osogbo, gbogbo ohun to wa lokan omokunrin eni odun mejidinlogbon, Olalekan Akeem ni bi yoo se ji foonu onifoonu lojo naa.
Loooto laniyan re wa simuse sugbon akara tu sepo fun un nitori bo se mu foonu ohun lasiru tu, ti owo si te e, leyin ti won fa a le awon agbofinro lowo lo foji bale ejo majistreeti lose to koja.
Gege bi asoju funleese olopa lori oro naa, Inspekito Fagboyinbo Abiodun se salaye funle ejo, nnkan aago mokanla aabo aaro ojo kejo osu kokanla ni olujejo ti huwa naa.
Mosalaasi White Mosque lagbegbe Iludun nilu Osogbo ni Fagboyinbo so pe Akeem ti huwa naa ati pe owoo foonu Lenovo to ji to egberun lona meedogbon naira eleyii to je ti Ogbeni Mohammad Abdulrasheed.
Fagboyinbo ni iwa olujejo naa lodi, bee lo si nijiya labe abala kerinlelogbon ofin irinwo din mewa tiwa odaran ti odun 2003 tipinle Osun.
Nigba ti won ka esun kansoso to nii se pelu ole jija si Akeem leti, o ni oun jebi esun naa sugbon ko ni agbejoro kankan lati gbenuso fun un nile ejo.
Nigba ti adajo majistreeti naa, Olowolagba Olubukola woye esun ti won fi kan olujejo, o ni ki won loo fi pamo sogba ewon fun osu mesan gbako laifaaye faini sile fun un.

No comments:

Post a Comment