To ba je pe awon tokotiyawo kan nilu Ileefe mo pe ohun ti yoo je igbeyin igbese ti won gbe lodun 2009 niyii ni, boya eedi ko nii di awon mejeeji, enikan a lanfaani lati si enikeji leti lojo naa.
O pe ti obinrin onisowo epo pupa kan, Bukola Taiwo ti ma n ra epo pupa pamo si sakani awon tokotaya yii gege bi a se gbo. Sugbon lasiko kan to ra epo yii lawon tokotiyawo naa, Fatai Jimoh ati Lateefat Jimoh, owo sa feere die lowoo won, won ta die lara epo naa nireti pe awon yoo ti da a pada ko too di pe obinrin onisowo yii a de.
Leyin ti won ta epo yii tan, ko si ona abayo kankan fun won, bee ni obinrin onisowo yii de lojo kejila osu kejo odun 2009, sugbon ki asiri ma baa tu, awon tokotiyawo yii, gege bi awon agbejoro se so ni kootu gbimopo, won si pa obinrin naa laarin oru.
Ariwo bi obinrin yii se n woya ija pelu awon alejo oran to ni loruganjo ohun lo ji awon ara agbegbe naa, sugbon ki owo too te awon olujejo yii, ohun rere ti baje, obinrin yii ti je Olorun nipe.
Leyin ti won pa obinrin yii tan ni won tun ko owo to to egberun lona mejidinlaadota naira ninu igbanu to so modi loru ojo naa.
Latigba yen ni won si ti wa lakolo olopa ko too di pe igbejo bere lori oro won lojo keji osu kefa odun 2014.
Ogbeni Moses Faremi ni agbejoro to soju ijoba ninu oro naa, esun meta otooto to nii se peluu igbimopo huwa buburu, ole jija ati ipaniyan ni won fi kan awon olujejo mejeeji naa.
Faremi salaye pe labule Ikeketu loji ona garaaji olode nijoba ibile Guusu Ife lawon olujejo ti huwa naa.
O ni ohun ti won se naa lodi, bee lo si nijiya labe ofin iwa odaran ti orileede yii ti odun 2000.
Laarin awon asiko igbejo naa, eleri merin otooto ni agbejoro funjoba pe. Awon naa ni inspekito olopa kan, onisegun oyinbo kan latileewosan UCH ni Ibadan, Baale Ikeketu nibi to ti sele ati araadugbo ibe kan to gbo si.isele naa.
Leyin atotonu opolopo odun, adajo ile ejo giga naa, Onidajo Onibokun rii pe awon olujejo jebi esun ti won fi kan won.
O waa pase pe ko won yegi fun awon mejeeji titi ti emi yoo fi bo laraa won.
No comments:
Post a Comment