Awon odomokunrin meji; Hamzat Hammed ati Oke Odunayo ti foju bale ejo majistreeti ilu Osogbo lori esun pe won n mugbo ninu ogba ileewe kan nilu Osogbo lasiko ti awon omoleewe si n keko lowo.
Hammed omo odun metalelogun ati Odunayo omo odun merindinlogoji ni awon olopa fi panpe ofin mu lori esun pe won n huwa to le da omi alaafia ileewe ru.
Gege bi agbejoro funleese olopa lori oro naa, Inspekito Fagboyinbo Abiodun se so, aago mejila osan ojo kesan osu kejila odun yii ni awon olujejo huwa naa ninu ogba ileewe Christ Africa Middle School lagbegbe Africa nilu Osogbo.
Fagboyinbo ni koda nigba ti igbo tawon eeyan yii pelu awon akegbee won ti won ti salo bayii n mu wo won lara, se ni Hammed koju ija si okunrin kan to n je Azeez Olaoluwa, to si da ogbe sii lapa osi.
O fi kun oro re pe iwa awon olujejo ohun lodi, bee lo si nijiya labe ofin iwa odaran ti odun un 2003 tipinle Osun.
Nigba ti won ka esun meteeta to nii se pelu igbimopo huwa buburu, dida omi alaafia agbegbe ru ati ija jija ti won fi kan won si won leti, won ni awon ko jebi awon esun naa.
Bakan naa ni agbejoro won, A.A.Popoola ati J.P. Jones ro ile ejo lati faaye beeli sile fun won nitoripe won ko tii jebi awon esun ti won fi kan won ayafi igba tile ejo ba so bee.
Ninu idajo re, Majistreeti Olusola Aluko faaye beeli sile fawon olujejo kookan pelu egberun lona aadota naira ati oniduro meji meji ni iye kannaa.
Leyin eyi lo sun igbejo siwaju di ojoketadinlogun osu keji odun un 2017.
Thursday, 22 December 2016
Hammed atore re n mugbo nileewe, ni won ba foju bale ejo
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment