IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 31 August 2017

Afi k'Olorun maa so wa o! Won tun ri ibuba awon apanisowo miin ni Mushin

Laiti pe osu kan ti won sawari ibuba awon apanisowo meji leralera lagbegbe Obadeyi ni Ijaiye-Ojokoro ati ni Ile Zik loju ona Eko si Abeokuta, won tun ti ri ibomiin tawon amookunsika yii ti n sose lagbegbe Challenge ni Mushin nilu Eko yii kannaa.
A gbo pe ninuu palapala kan tenikeni ko lee fura si lawon eeyan ohun ti n sise ibi won. 
Ibi ti won n lo ohun lo loo jasi ileese nla kan to ti di apati latojo to ti pe. Opolopo abere ni won ba nibe eleyii tawon eeyan gbagbo pe won fi maa n gun awon to ba ko si won lowo lati le ra won niye. 
Loju ese lawon araalu ti dana sun okan ninu awon afurasi naa laaye nigba ti awon olopa se opolopo wahala ki won too ri awon afurasi meji to ku gba lowo awon ero ti won pe pitimu sibe. 

No comments:

Post a Comment