IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 30 August 2017

Egberun Ajimobi ko le da mi duro lati je Olubadan - Ladoja

Gomina tele funpinle Oyo to tun je Osi Olubadan lowolowo, Oloye Rashidi Ladoja ti so pe to ba wu Olorun koun de ipo Olubadan, egberun Gomina Ajimobi ko lee da oun duro laelae.
Ninu atejade kan lati owoo akowe iroyin Ladoja, Ogbeni Latinwo lo ti so pe bi Ajimobi se so araa re di afobaje osangangan laika ilana yiyan Oba to wa nilu Ibadan bayii si ko seyin erongba re lati fiyaje awon to ti mu lota.
Ladoja ni digbi loun wa gege bii Osi Olubadan nitori oun ko fe Oba alafefeye ti Ajimobi sese fawon kan je lojo isegun to koja.
O fi kun oro re pe bo ba je ife Olorun, o di dandan koun de ipo Olubadan tilu Ibadan.

No comments:

Post a Comment