Adajo majistreeti kan nilu Osogbo ti pase pe ki Akeem Yusuf loo sodun Ileya logba ewon ilu Ilesa latari esun sise ayederu iwe agbejoro ti won fi kan an.
Akeem nileese olopa ipinle Osun fesun kan pe o se ayederu leta ati ami idanimo to je ti Barista Gbadebo to wa lagbegbe Kola-Balogun nilu Osogbo.
Ojo ketala osu keta odun yii la gbo pe Akeem ko leta ebe kan si ofiisi to n sojuu orileedee United Kingdom lorileede yii, to si bu owo lu leta naa bii eni pe agbejoro Gbadebo lo ko o.
Agbejoro funleese olopa lori esun naa, Lamidi Rasaq so pe iwa ti olujejo to je omo odun merinlelogoji ohun hu lodi sofin, sugbon agbejoro re, Abimbola Ige so pe okunrin naa ko huwa odaran ri.
Ninu idajo Majistreeti Olubukola Awodele so pe ki won loo fi Akeem pamo sogba ewon ilu Ilesa fun odun kan tabi ko san owo itanran egberun lona mewa naira.
No comments:
Post a Comment