Oro di bo o lo o ya lona laaro oni lagbegbe Gbeja ni Oke Baale nilu Osogbo nigba tawon toogi dojuko awon olopa, to si je pe die lo ku ki won danasun ago olopa to wa nibe.
Wahala ohun bere lasiko ti awon olopa agbegbe naa fee fi panpe ofin gbe okunrin kan to n je Segun, ti inagije re n je Emir. A gbo pe olori awon toogi ni Emir, gbogbo igba lawon araalu si maa n mu ejoo re lo sago olopa.
Ibikan ti Emir pelu awon egbee re ti loo sose lale ojoo satide la gbo pe awon yen loo fejo sun awon olopa, nigba tawon olopa si ti mo pe Emir atawon egbee re maa n lo gba boolu laraaro lo je ki won wa a lo sibe.
Sugbon nigba ti won debe se lawon akeegbe Emir dojuko awon olopa ti won si n leri pe ko seni to le mu oga awon kuro nibe. Ariwo yii ni won n pa lowo ti olopa kan fi fa ibon ilewo yo nitori pe oro naa ti fee di wahala nla, bayii lawon toogi ohun sa seyin lati tunramu.
Pelu ada ati apola igi la gbo pe awon toogi yii pada laarin iseju marun, won si dojuko awon olopa naa. Bawon olopa se n feyin rin lo sibi ti moto won wa la gbo pe awon omo yii tun n tele won.
Lati le da ipaya sokan awon toogi yii lo mu kolopa kan yinbon soke lati fi tu won ka, sugbon iyalenu lo je, gege bi enikeni toro naa soju e se so pe ogangan aya Emir nibon naa se.
Won ko tii gbe Emir dele iwosan to fi jade laye. Bayii lawon akeegbe e fon sojuu titi, bi won se n dana sun taya ni won n fo igo mole, won si forile ago olopa Oke baale lati dana sun un, idi niyen tawon yen fi ranse si olu ileese won to wa ni Ring road pe ki won ko awon oko ayeta wa.
Ninu oro tire, alukooro ileese olopa, Folasade Odoro ni ni kete tawon ti gba ipe pe awon toogi bii aadota eleyii ti Akaje, Ora ati Epo ko sodi n da wahala sile lagbegbe Aloyunkewu, Imole n fe Alaafia, Lion Junction, Ori Eeru, Oke Allahu ni Oke Baale lawon ti lo sibe.
O ni komisanna olopa, Ogbeni Fimihan Adeoye ti pase pe ki iwadi kikun bere lori isele naa.
Sunday, 3 September 2017
Eyi ni bi ibon awon olopa se pa Emir nilu Osogbo
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment