Araba awo tilu Osogbo, Oloye Ifayemi Elebuibon ti so pe okunrin to ba pinnu lati fe Omoobabinrin Zaynab Otiti-Obanor to di Wuraola leyin to fe Ooni ti Ileefe, Oba Adeyeye Ogunwusi, gbodo mura gidigidi nitori pe ohun meta otooto lo se e se ko sele sii.
Laipe yii lo di mimo pe igbeyawo aarin Ooni ati aya re ohun, Wuraola ti fori sanpon. Bo tile je pe Ooni ko tii so ohunkohun lori oro yii, sugbon Wuraola ti soro lori itakun ayelujara pe ko si ibasepo kankan mo laarin oun ati oriade naa.
Latari idi eyi, Oloye Ifayemi ni olori tele naa gbodo gbe awon igbese kan nilana ti asa ibile ko too di pe yoo fe oko miin.
Elebuibon ni kii se olori tele ohun ni nnkan yoo se bikose okunrin to ba ba a lajosepo.
Baba yii ni o ni lati beere lowo ifa iru igbese to ye ko gbe lati le dena iku aitojo lori okunrin naa. Bakannaa ni aisan airotele le kolu iru okunrin bee tabi ko ma gberi mo laelae.
Sunday, 3 September 2017
Ohun to le sele si oko to ba fe Wuraola, Iyawo Ooni tele - Elebuibon
.Unknown
.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment