Tolulope Emmanuel, Osogbo
Asofin to n soju awon eeyan agbegbe Ariwa Ife nile igbimo asofin ipinle Osun, Onorebu Babatunde Olatunji ti ni ko si nnkan meji to je ohun logun ju awon ona tidagbasoke ti ko legbe yoo se ba awon eeyan agbegbe toun n soju fun lo.

Onorebu yii soro ohun lasiko to n gbe milioonu kan naira kale fawon eeyan agbegbe naa lati sanwo ti ajo CSDP so pe ki won san lati le lanfaani si gbongan ayeye nla (civic center) ti won n fe lagbegbe naa.
O ni ojo ti pe tawon eeyan agbegbe ohun ti n pongbe gbongan naa ati pe o je idunnu oun pe asiko toun ni ala naa yoo wa simuse.
Olatunji ni egberun lona eedegberin naira gan an lowo ti CSDP sugbon oun fe ki won lo egberun lona oodunrun naira to ku lati fi ra aga ati tabili sinuu gbongan naa.
O waa gbosuba fun akowe CSDP fun anfaani nla naa, bee lo yinjoba Aregbesola lawo fun ona to n gba mutesiwaju ba ipinle Osun.
Bee lo ro gbogbo awon eeyan re atawon ara ipinle Osun lati fowosowopo pelu Gomina Aregbesola lori erongba re lati gbe ipinle Osun doke tente.
Ninu oro idupe re, alaga egbe Edunabon Progressives Union, Omooba Adeniran Abodunde, o gbosuba nla fun Onorebu Olatunji fun igbese akin to gbe lori ilu e, bee lo si ro gbogbo awon ti ori segi ola fun lati sawokose rere lara asofin naa.

Oye kayin Asofin wa pe won se daradara, Ki Olorun tubo ma ran won lowo
ReplyDelete