Tolulope Emmanuel, Osogbo
Ajo to n gbogun ti iwa ibaje atawon esun miin lorileede yii, Independent Corrupt Practices and Other Related Offences (ICPC) ti so pe ko si ooto ninuu esun tawon kan fi n kan Gomina Aregbesola pe o se owo iranwo tijoba apapo fun awon ijoba ipinle lodun 2015 basubasu.
Ajo naa nipase leta to ko laipe yii so pe awon nnkan tijoba apapo fe ki Aregbesola lo owo to din die ni bilioonu marunlelogbon ohun si gan an ni won lo fun.
Gege bi eni to je adari leka iwadi ajo naa, Adebayo Kayode se so, owo osu awon osise ijoba, owo ifeyinti awon osise nipinle atijoba ibile pelu owo awon omo ajo Oyes ti owo iranwo ohun wa fun gan an l'Aregbesola lo won fun.
Adebayo waa bu enu ate lu iwe esun kan ti egbe Emancipation of the people of Osun State ko pe Aregbesola na owo naa ninakuna, o ni ko si eri kankan lati gbe esun naa lese.
Bee naa ni komisanna feto iroyin nipinle Osun, Onorebu Adelani Baderinwa so pe kawon olote loo sinmi lori oro Gomina Aregbesola, o si ni o ye kijiya maa wa fun enikeni to ba ko nnkan ti ko nitumo nipa ijoba.
Monday, 25 September 2017
Oju ti awon olote! Ajo ICPC ni Aregbesola kii se oninakuna
Tags
# iroyin
# iroyin-oselu
.Unknown
.
iroyin-oselu
Labels:
iroyin,
iroyin-oselu
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment