IROYIN YAJOYAJO

Thursday, 7 September 2017

Komisanna Aregbesola fee sayeye ojoobi losibitu

Inu ogba osibitu Obafemi Awolowo University Teaching Hospital nilu Ileefe ni Komisanna tele feto isuna nipinle Osun, Dokita Adewale Bolorunduro yoo ti se ayeye ojoobi re loni.
Gege bi akosemose ninu isiro owo naa, to tun je omobibi ile Ijesa ohun se wi, dipo ki oun maa dana repete fawon ore ati ojulumo toun mo pe won lowo lowo loun se kuku pinnu lati loo se ayeye naa laarin awon alaisan.
Dokita Adewale ni aarin awon toun yoo ti sayeye naa loni ni awon alabiyamo to je pe airowo san funleewosan ko je ki won lanfaani lati sekomo omo won ninu ile araa won.
O waa ro gbogbo awon eleyinju aanu ti won ri jaje lawujo lati sawokose oun nipa riran awon alaini lowo dipo ki won maa re isun da sinu ibu.

No comments:

Post a Comment