IROYIN YAJOYAJO

Wednesday, 6 September 2017

Tadese pariwo ni kootu, "Torii pe a ko se nnkan ti Oluwo fe lo se ko ba wa"


Awon tegbontaburo ti won je omobibi ilu Iwo ti so fawon oniroyin ni kootu pe se ni Oluwo tilu Iwo, Oba Abdulrasheed Akanbi ko ba awon tori pe awon ko lati se nnkan to fe kawon se.
Tegbontaburo naa, Arolu Akeem Tadese ati Cology Akeem Tadese lawon olopa safihan won niwaju ile ejoo majistreeti kan nilu Osogbo lori esun pe won so olopa lokuta lori.
Gege bi agbejoro funleese olopa, Sunday God se so, ojo kejila osu kejila odun yii ni awon olujejo gbimopo ti won si so olopa kan, Sajenti Taiwo Ikusanmi lokuta lori nilu Iwo.
Sunday ni iwa tawon tegbontaburo naa hu lodi sofin bee lo si nijiya nla.
Ninu idajo re leyin ti agbejoro fawon olujejo, Naheem Adekunle ro ile ejo lati faaye beeli sile fun won, Majistreeti Sodamade Fatimoh faaye beeli sile fun won pelu egberun Lona eedegbeta naira ati oniduro kan ni iye kannaa.
Leyin eyi lo sun igbejo siwaju di ojo kokanla osu kesan odun yii.
Nigba ti won ko awon olujejo mejeeji yii kuro ninuu kootu, won salaye fawon oniroyin pe se ni Oba Akanbi so pe dandan kawon fa Sooko sile ninuu molebi awon ti awon si so fun un pe awon ko je.
Won fi kun oro won pe enikan ninuu molebi awon to so pe oun fee je ni gbogbo molebi keyin si sugbon to je pe se ni Oluwo ran awon toogi wa sile awon.
Awon mejeeji ni "Ohun ti a ri leyin re ni pe awon olopa waa mu wa



No comments:

Post a Comment