IROYIN YAJOYAJO

Sunday, 10 September 2017

L'Osogbo, moto oti ja wonuu mosalasi

Ori lo ko awon olujosin Mosalasi Gaji lagbegbe Olonkooro nilu Osogbo yo nigba ti moto nla kan to ko otii bia so ijanu re nu, to si loo foriso mosalasi ohun.
Lasiko ti irun kiki nlo lowo, tawon olujosin si po ninu mosalasi daada la gbo pe isele naa sele.
Bo tile je pe isele naa ba won lojiji, sibe Olorun ko je kenikeni farapa nibe.
A gbo pe se ni igo oti bia fo sile yannayanna ninuu mosalasi ohun ati agbegbe re.
Bakannaa ni omi oti bia fon si gbogbo awon tisele naa ka monuu mosalasi lara.
Ohun to sele ohun bi awon ti won wa nibe ninu, bi kii ba se ti awon aafa atawon agbaagba ti won tete petu si won ninu, wahala nla loro naa iba da sile.
Alukoro funleese olopa ipinle Osun, Arabinrin Folasade Odoro ni awon ti gbo nipa isele naa ati pe iwadi ti bere lori e logan.

No comments:

Post a Comment