Awon olopa Igando Division nilu Eko ti wo okunrin kan to n pe araa re ni iranse Olorun lo sile ejo lori esun ole jija ati fifi oogun gba nnkan oninnkan.
Pasito Gbenga Oyelere lowo te leyin ti iye obinrin kan to fi oogun gba oko ayokele RAV 4 SUV lowo e si.
Gafaru Alani Street, lagbegbe Akesan nilu Eko nisele naa ti sele, nibe la gbo pe Pasito Oyelere ti gbadura fun omobinrin eni odun mejilelogoji kan, Yemi Ariwodola.
Leyin adura ni pasito so fun obinrin yii pe ko figbagbo gbe moto re kale gege bii gbigbin eso sinu aye oun ati pe to ba se e pelu igbagbo, Logan nisegun re yoo de.
A gbo pe obinrin yii gbe moto re kale to si tun fun pasito ni egberun lona ogorin naira lati maa fi tun moto naa se, bayii lo wo moto pada sile e.
Leyin ojo die tise iyanu kankan ko sele laye obinrin yii ni iyee re si, o beere lowo awon alajogbele re pe nibo ni moto jiipu oun wa, won si so fun un pe o ti fi tore fun pasito onise iyanu.
Bayii ni won morile ago olopa, nigba tawon olopa de odo Pasito Oyelere, o so pe ki won se oun jeje ati pe abule oun nipinle Kwara loun gbe moto naa pamo si.
Ni kootu majistreeti tagbegbe Ejigbo nilu Eko, Pasito Oyelere loun ko jebi esun naa, Adajo J.O.E Adeyemi faaye beeli sile fun un pelu egberun lona ogorun naira pelu oniduro meji ni iye kannaa.
O wa sun igbejo siwaju di ojo kokandinlogun osu kesan odun yii.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment