IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 23 September 2017

O pari! Ile Odofin Osogbo ni Basiru Ajibola kii s'omo ale, omo awon ni

Lori oro kan to n ja rahinrahin nile laipe yii nipa orirun komisanna feto idajo nipinle Osun, Dokita Ajibola Basiru, awon agbaagba agboole Odofin nilu Osogbo ti ni ojulowo omo awon ni komisanna naa. 
Lojo kinni osu kesan odun yii ni aheso naa bere lasiko ede aiyede kan to be sile ni Yidi tawon musulumi ilu Osogbo ti loo sadura odun Ileya. 
Amo sa, Odofin tilu Osogbo, Oloye Akin Opatunde ti so lasiko ipade molebi naa to waye lojule kejila lopopona Ibokun nilu Osogbo pe obi ti ko ba sunwon nikan lo le fowoleran tenikeni ba n naka aleebu somo re. 
Oloye Opatunde ni ile baba nla Basiru lawon ti koko joko sepade awon omo ile Odofin nilu Osogbo ko too di pe won ko Aruru ti won n lo bayii. 
Baba yii ni gbogbo amuye awon omo ile Odofin lo pe sara Ajibola Basiru, eleyii to ni o mu un je amuyangan fun gbogbo ile.
O waa ro gbogbo awon omo ilu Osogbo lati gba alaafia laaye ati pe awon agbaagba ti n sise lowo lori ona tisokan yoo fi tubo maa joba laifi ti oselu se.

No comments:

Post a Comment