IROYIN YAJOYAJO

Saturday, 23 September 2017

E ma paro mo mi o, emi o sepade kankan pelu Ali Modu Sheriff o - Oyegun



Alaga apapo fegbe oselu APC lorileede yii, Oloye John Odigie Oyegun ti ni iro to jinna soooto niroyin kan to n lo kaakiri pe oun wa pelu igbakeji aare orileede yii, Ojogbon Yemi Osibajo nibi tawon ti sepade idakonko pelu alaga fegbe PDP tele tile ejo yo nipo, Senato Ali Modu Sheriff.
Oyegun ni oun le fi gbogbo enu so pe odun meji seyin loun ti fojukan Sheriff, bee loun ko mo si ipade kankan laarin re (Sheriff) ati Ojogbon Osibajo.
O fi kun oro re pe loooto nilekun egbe naa si sile gbayau fun enikeni to ba fee darapo mo awon, sugbon oun ko tii sepade kankan pelu Seneto Sheriff gege bi awon kan se n so kaakiri.
Oyegun ni awon aponmiokerutodo ni won n gbe iroyin naa kaakiri nitori oun ko se ipade kankan pelu Osibajo lojo ti won so yii ka too wa so ti Ali Modu Sheriff.

3 comments: